Native Bible

Psalms 40:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.

Psalms 40:11 in English

Psalms 40:11 · Berean Standard Bible

O LORD, do not withhold Your mercy from me; Your loving devotion and faithfulness will always guard me.

Context

9Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrín àwùjọ ńlá; wò ó, èmi kò pa ètè mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ Olúwa. 10Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi; èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ. Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá. 11Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé. 12Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà. 13Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ Olúwa, láti gbà mí là; Olúwa, yára láti ràn mí lọ́wọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.