Saamu 40:15
Psalms 40:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!” ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
Psalms 40:15 in English
Psalms 40:15 · Berean Standard Bible
May those who say to me, “Aha, aha!” be appalled at their own shame.
Context
13Jẹ́ kí ó wù ọ́,
ìwọ Olúwa,
láti gbà mí là;
Olúwa,
yára láti ràn mí lọ́wọ́. 14Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì
kí wọn kí ó sì dààmú;
àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun
jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n,
àwọn tí ń wá ìpalára mi. 15Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!”
ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn. 16Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ
kí ó máa yọ̀
kí inú wọn sì máa dùn sí ọ;
kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ
kí o máa wí nígbà gbogbo pé,
“Gbígbéga ni Olúwa!” 17Bí ó ṣe ti èmi ni,
tálákà àti aláìní ni èmi,
ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi
àti ìgbàlà mi;
má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́,
ìwọ Ọlọ́run mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.