Saamu 39:8
Psalms 39:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo. Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn àwọn ènìyàn búburú.
Psalms 39:8 in English
Psalms 39:8 · Berean Standard Bible
Deliver me from all my transgressions; do not make me the reproach of fools.
Context
6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ. 7“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ. 8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú. 9Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é. 10Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.