Saamu 39:6
Psalms 39:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
Psalms 39:6 in English
Psalms 39:6 · Berean Standard Bible
Surely every man goes about like a phantom; surely he bustles in vain; he heaps up riches not knowing who will haul them away.
Context
4“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín. 5Ìwọ ti ṣe ayé mi
bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
ní iwájú rẹ.
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela. 6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ. 7“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ. 8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.