Native Bible

Psalms 39:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.

Psalms 39:4 in English

Psalms 39:4 · Berean Standard Bible

“Show me, O LORD, my end and the measure of my days. Let me know how fleeting my life is.

Context

2Mo fi ìdákẹ́ ya odi; mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere; ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i. 3Àyà mi gbóná ní inú mi. Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn; nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀: 4“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín. 5Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ. Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela. 6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.