Native Bible

Psalms 39:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ. Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

Psalms 39:5 in English

Psalms 39:5 · Berean Standard Bible

You, indeed, have made my days as handbreadths, and my lifetime as nothing before You. Truly each man at his best exists as but a breath. Selah

Context

3Àyà mi gbóná ní inú mi. Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn; nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀: 4“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín. 5Ìwọ ti ṣe ayé mi bí ìbú àtẹ́lẹwọ́, ọjọ́ orí mi sì dàbí asán ní iwájú rẹ. Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela. 6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji. Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán; wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ, wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ. 7“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, Olúwa, kín ni mo ń dúró dè? Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.