Native Bible

Psalms 39:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.

Psalms 39:10 in English

Psalms 39:10 · Berean Standard Bible

Remove Your scourge from me; I am perishing by the force of Your hand.

Context

8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo. Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn àwọn ènìyàn búburú. 9Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́; èmi kò sì ya ẹnu mi, nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é. 10Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ. 11Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo. 12“Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi. Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ, àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.