Saamu 35:14
Psalms 35:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀ bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni. Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
Psalms 35:14 in English
Psalms 35:14 · Berean Standard Bible
I paced about as for my friend or brother; I was bowed down with grief, like one mourning for his mother.
Context
12Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;
láti sọ ọkàn mi di òfo. 13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;
mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.
Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi; 14èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀
bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni.
Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́
bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀. 15Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ;
wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀.
Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́. 16Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ
wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.