Native Bible

Psalms 35:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n fi búburú san ìre fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo.

Psalms 35:12 in English

Psalms 35:12 · Berean Standard Bible

They repay me evil for good, to the bereavement of my soul.

Context

10Gbogbo egungun mi yóò wí pé, “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa? O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ, tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?” 11Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde; wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀. 12Wọ́n fi búburú san ìre fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo. 13Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi; 14èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀ bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni. Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.