Saamu 35:10
Psalms 35:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo egungun mi yóò wí pé, “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa? O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ, tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
Psalms 35:10 in English
Psalms 35:10 · Berean Standard Bible
All my bones will exclaim, “Who is like You, O LORD, who delivers the afflicted from the aggressor, the poor and needy from the robber?”
Context
8Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀. 9Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,
àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀. 10Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
“Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?
O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?” 11Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;
wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀. 12Wọ́n fi búburú san ìre fún mi;
láti sọ ọkàn mi di òfo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.