Saamu 35:8
Psalms 35:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì. Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀; kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
Psalms 35:8 in English
Psalms 35:8 · Berean Standard Bible
May ruin befall them by surprise; may the net they hid ensnare them; may they fall into the hazard they created.
Context
6Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,
kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn! 7Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,
ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi. 8Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀. 9Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,
àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀. 10Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
“Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?
O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.