Saamu 27:7
Psalms 27:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Olúwa, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn,
Psalms 27:7 in English
Psalms 27:7 · Berean Standard Bible
Hear, O LORD, my voice when I call; be merciful and answer me.
Context
5Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. 6Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa. 7Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Olúwa,
ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn, 8Ọkàn mi wí pé, “Wá ojú u rẹ̀!”
Ojú rẹ, Olúwa, ni ti èmí ń wá. 9Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.