Native Bible

Psalms 27:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

Psalms 27:5 in English

Psalms 27:5 · Berean Standard Bible

For in the day of trouble He will hide me in His shelter; He will conceal me under the cover of His tent; He will set me high upon a rock.

Context

3Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le. 4Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. 5Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. 6Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa. 7Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Olúwa, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.