Saamu 27:4
Psalms 27:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
Psalms 27:4 in English
Psalms 27:4 · Berean Standard Bible
One thing I have asked of the LORD; this is what I desire: to dwell in the house of the LORD all the days of my life, to gaze on the beauty of the LORD and seek Him in His temple.
Context
2Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. 3Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
nínú èyí ni ọkàn mi yóò le. 4Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. 5Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. 6Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.