Native Bible

Psalms 139:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?

Psalms 139:21 in English

Psalms 139:21 · Berean Standard Bible

Do I not hate those who hate You, O LORD, and detest those who rise against You?

Context

19Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀. 20Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán! 21Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ? 22Èmi kórìíra wọn ní àkótán; èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi. 23Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.