Saamu 126
Psalms 126 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá. 2Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn. 3Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
nítorí náà àwa ń yọ̀. 4Olúwa mú ìkólọ wa padà,
bí ìṣàn omi ní gúúsù. 5Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
yóò fi ayọ̀ ka. 6Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
yóò sì ru ìtí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.