Saamu 109:3
Psalms 109:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí
Psalms 109:3 in English
Psalms 109:3 · Berean Standard Bible
They surround me with hateful words and attack me without cause.
Context
1Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún,
má ṣe dákẹ́, 2nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
ti ya ẹnu wọn sí mi
wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi. 3Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
wọ́n bá mi jà láìnídìí 4Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà. 5Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.