Native Bible

Proverbs 4:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.

Proverbs 4:13 in English

Proverbs 4:13 · Berean Standard Bible

Hold on to instruction; do not let go. Guard it, for it is your life.

Context

11Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà. 12Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. 13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ. 14Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi. 15Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀; yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.