Native Bible

Proverbs 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.

Proverbs 4:12 in English

Proverbs 4:12 · Berean Standard Bible

When you walk, your steps will not be impeded; when you run, you will not stumble.

Context

10Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn. 11Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà. 12Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. 13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ. 14Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.