Òwe 4:14
Proverbs 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
Proverbs 4:14 in English
Proverbs 4:14 · Berean Standard Bible
Do not set foot on the path of the wicked or walk in the way of evildoers.
Context
12Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́
nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. 13Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;
tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ. 14Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú
tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi. 15Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;
yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ. 16Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,
wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.