Native Bible

Proverbs 30:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.

Proverbs 30:6 in English

Proverbs 30:6 · Berean Standard Bible

Do not add to His words, lest He rebuke you and prove you a liar.

Context

4Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀. 5“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù; òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn. 6Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́. 7“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú. 8Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.