Òwe 30:7
Proverbs 30:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú.
Proverbs 30:7 in English
Proverbs 30:7 · Berean Standard Bible
Two things I ask of You— do not refuse me before I die:
Context
5“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;
òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn. 6Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,
àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́. 7“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa;
má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú. 8Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi;
má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀,
ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan. 9Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ
kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’
Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè
kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.