Òwe 30:3
Proverbs 30:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì.
Proverbs 30:3 in English
Proverbs 30:3 · Berean Standard Bible
I have not learned wisdom, and I have no knowledge of the Holy One.
Context
1Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli.
Sí Itieli àti sí Ukali. 2“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn;
n kò ní òye ènìyàn. 3Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n
tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì. 4Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀?
Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀?
Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ?
Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀?
Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀?
Sọ fún mi bí o bá mọ̀. 5“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù;
òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.