Native Bible

Proverbs 30:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn; n kò ní òye ènìyàn.

Proverbs 30:2 in English

Proverbs 30:2 · Berean Standard Bible

Surely I am the most ignorant of men, and I lack the understanding of a man.

Context

1Àwọn ọ̀rọ̀ Aguri ọmọ Jake, ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Itieli. Sí Itieli àti sí Ukali. 2“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn; n kò ní òye ènìyàn. 3Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì. 4Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.