Òwe 28:17
Proverbs 28:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
Proverbs 28:17 in English
Proverbs 28:17 · Berean Standard Bible
A man burdened by bloodguilt will flee into the Pit;* let no one support him.
Context
15Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀
ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára. 16Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú,
ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́. 17Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn
yóò máa joró rẹ̀ títí ikú
má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́. 18Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là,
ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì. 19Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.