Native Bible

Proverbs 28:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́.

Proverbs 28:16 in English

Proverbs 28:16 · Berean Standard Bible

A leader who lacks judgment is also a great oppressor, but he who hates dishonest profit will prolong his days.

Context

14Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà. 15Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára. 16Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú, ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́. 17Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́. 18Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.