Òwe 28:15
Proverbs 28:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára.
Proverbs 28:15 in English
Proverbs 28:15 · Berean Standard Bible
Like a roaring lion or a charging bear is a wicked ruler over a helpless people.
Context
13Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà. 14Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà gbogbo
ṣùgbọ́n ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà. 15Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Beari tí ń halẹ̀
ni ènìyàn búburú tí ń jẹ ọba lórí àwọn aláìlágbára. 16Ọmọ-aládé tí ó ṣe aláìmòye púpọ̀ ní ń ṣe ìwà ìkà púpọ̀ pẹ̀lú,
ṣùgbọ́n èyí tí ó kórìíra ojúkòkòrò yóò mú ọjọ́ rẹ̀ pẹ́. 17Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn
yóò máa joró rẹ̀ títí ikú
má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.