Òwe 28:19
Proverbs 28:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì.
Proverbs 28:19 in English
Proverbs 28:19 · Berean Standard Bible
The one who works his land will have plenty of food, but whoever chases fantasies will have his fill of poverty.
Context
17Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn
yóò máa joró rẹ̀ títí ikú
má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́. 18Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là,
ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì. 19Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì. 20Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an
ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà. 21Ojúsàájú ṣíṣe kò dára,
síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.