Native Bible

Proverbs 28:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà.

Proverbs 28:20 in English

Proverbs 28:20 · Berean Standard Bible

A faithful man will abound with blessings, but one eager to be rich will not go unpunished.

Context

18Ẹni tí ń rìn déédéé ní yóò là, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà ni yóò ṣubú lójijì. 19Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì. 20Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà. 21Ojúsàájú ṣíṣe kò dára, síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan. 22Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.