Òwe 28:22
Proverbs 28:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.
Proverbs 28:22 in English
Proverbs 28:22 · Berean Standard Bible
A stingy man * hastens after wealth and does not know that poverty awaits him.
Context
20Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an
ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà. 21Ojúsàájú ṣíṣe kò dára,
síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan. 22Ahun ń sáré àti là
kò sì funra pé òsì dúró de òun. 23Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn
ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ. 24Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè
tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,”
irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.