Native Bible

Proverbs 19:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.

Proverbs 19:3 in English

Proverbs 19:3 · Berean Standard Bible

A man’s own folly subverts his way, yet his heart rages against the LORD.

Context

1Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. 2Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀, tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà. 3Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa. 4Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 5Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.