Òwe 19:5
Proverbs 19:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
Proverbs 19:5 in English
Proverbs 19:5 · Berean Standard Bible
A false witness will not go unpunished, and one who utters lies will not escape.
Context
3Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;
síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa. 4Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;
ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 5Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,
ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́. 6Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;
gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́. 7Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì,
mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!
Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,
kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.