Native Bible

Proverbs 17:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.

Proverbs 17:21 in English

Proverbs 17:21 · Berean Standard Bible

A man fathers a fool to his own grief; the father of a fool has no joy.

Context

19Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun. 20Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú, ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu. 21Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n. 22Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ. 23Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.