Native Bible

Proverbs 17:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.

Proverbs 17:22 in English

Proverbs 17:22 · Berean Standard Bible

A joyful heart is good medicine, but a broken spirit dries up the bones.

Context

20Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú, ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu. 21Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn, kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n. 22Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ. 23Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po. 24Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú, ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.