Native Bible

Proverbs 14:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn.

Proverbs 14:25 in English

Proverbs 14:25 · Berean Standard Bible

A truthful witness saves lives, but one who utters lies is deceitful.

Context

23Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni. 24Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọn ṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá. 25Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn. 26Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára, yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀. 27Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.