Òwe 14:27
Proverbs 14:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
Proverbs 14:27 in English
Proverbs 14:27 · Berean Standard Bible
The fear of the LORD is a fountain of life, turning a man from the snares of death.
Context
25Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí là
ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn. 26Nínú ìbẹ̀rù Olúwa ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,
yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀. 27Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè,
tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú. 28Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,
ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun. 29Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,
ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.