Native Bible

Proverbs 13:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

Proverbs 13:22 in English

Proverbs 13:22 · Berean Standard Bible

A good man leaves an inheritance to his children’s children, but the sinner’s wealth is passed to the righteous.

Context

20Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára. 21Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo. 22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo. 23Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ. 24Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.