Òwe 13
Proverbs 13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ọlọ́gbọ́n ọmọ gba ẹ̀kọ́ baba rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò gbọ́ ìbáwí. 2Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn ohun rere,
ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn aláìṣòótọ́ ní ìwà ipá. 3Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù gbàù yóò parun. 4Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan,
ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn. 5Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú. 6Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú,
ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò. 7Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan
ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 8Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀
ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà. 9Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro,
ṣùgbọ́n fìtílà ènìyàn búburú ni a pa kú. 10Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni
ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn. 11Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i. 12Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀
ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè. 13Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀. 14Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè,
tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú. 15Òye pípé ń mú ni rí ojúrere,
ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́. 16Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀,
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn. 17Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdààmú
ṣùgbọ́n aṣojú olóòtítọ́ mú ìwòsàn wá. 18Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá. 19Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn
ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi. 20Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n
ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára. 21Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀,
ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo. 22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo. 23Ilẹ̀ ẹ tálákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìre oko wá
ṣùgbọ́n àìṣòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ. 24Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀
ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa bá a wí. 25Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn
ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.