Native Bible

Proverbs 13:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.

Proverbs 13:20 in English

Proverbs 13:20 · Berean Standard Bible

He who walks with the wise will become wise, but the companion of fools will be destroyed.

Context

18Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá. 19Ìfẹ́ tí a mú ṣẹ dùn mọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi. 20Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára. 21Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo. 22Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.