Native Bible

Proverbs 13:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú.

Proverbs 13:14 in English

Proverbs 13:14 · Berean Standard Bible

The teaching * of the wise is a fountain of life, turning one from the snares of death.

Context

12Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè. 13Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀. 14Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹ̀kùn ikú. 15Òye pípé ń mú ni rí ojúrere, ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìṣòótọ́ kì í tọ́jọ́. 16Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.