Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

Obadiah 1:9 in English

Obadiah 1:9 · Berean Standard Bible

Then your mighty men, O Teman, will be terrified, so that everyone in the mountains of Esau will be cut down in the slaughter.

Context

7Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ; àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.” 8Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau? 9A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà. 10Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ, a ó sì pa ọ run títí láé. 11Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ, tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.