Obadiah 1:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
Obadiah 1:8 in English
Obadiah 1:8 · Berean Standard Bible
In that day, declares the LORD, will I not destroy the wise men of Edom and the men of understanding in the mountains of Esau?
Context
6Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,
tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde. 7Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ
ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ,
àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;
àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,
ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.” 8Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,
Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,
àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau? 9A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani,
gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau
ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà. 10Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,
ìtìjú yóò bò ọ,
a ó sì pa ọ run títí láé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.