Obadiah 1:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau, tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
Obadiah 1:6 in English
Obadiah 1:6 · Berean Standard Bible
But how Esau will be pillaged, his hidden treasures sought out!
Context
4Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,
bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”
ni Olúwa wí. 5“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,
bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,
Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́,
wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?
Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,
wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀? 6Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,
tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde. 7Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ
ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ,
àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;
àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,
ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.” 8Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,
Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,
àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.