Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni Olúwa wí.

Obadiah 1:4 in English

Obadiah 1:4 · Berean Standard Bible

Though you soar like the eagle and make your nest among the stars, even from there I will bring you down,” declares the LORD.

Context

2“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 3Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’ 4Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni Olúwa wí. 5“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru, Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́, wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́? Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀? 6Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau, tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.