Obadiah 1:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
Obadiah 1:3 in English
Obadiah 1:3 · Berean Standard Bible
The pride of your heart has deceived you, O dwellers in the clefts of the rocks * whose habitation is the heights, who say in your heart, ‘Who can bring me down to the ground?’
Context
1Ìran ti Obadiah.
Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.
Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,
“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.” 2“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;
ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 3Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,
ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,
tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,
ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,
‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’ 4Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,
bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”
ni Olúwa wí. 5“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,
bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,
Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́,
wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?
Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,
wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.