Obadiah 1:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ, tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.
Obadiah 1:11 in English
Obadiah 1:11 · Berean Standard Bible
On the day you stood aloof while strangers carried off his wealth and foreigners entered his gate and cast lots for Jerusalem, you were just like one of them.
Context
9A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani,
gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau
ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà. 10Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,
ìtìjú yóò bò ọ,
a ó sì pa ọ run títí láé. 11Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,
ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,
tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ,
tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,
ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn. 12Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,
ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀
ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,
ní ọjọ́ ìparun wọn
ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀
ní ọjọ́ wàhálà wọn. 13Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,
ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀
nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,
ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.