Native Bible

Numbers 34:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ”

Numbers 34:12 in English

Numbers 34:12 · Berean Standard Bible

Then the border will go down along the Jordan and end at the Salt Sea. This will be your land, defined by its borders on all sides.”

Context

10Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ tiyín ní ìhà ìlà-oòrùn láti Hasari-Enani lọ dé Ṣefamu. 11Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn. 12Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ” 13Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀. 14Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.