Native Bible

Numbers 34:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn.

Numbers 34:14 in English

Numbers 34:14 · Berean Standard Bible

For the tribes of the Reubenites and Gadites, along with the half-tribe of Manasseh, have already received their inheritance.

Context

12Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ” 13Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀. 14Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn. 15Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.” 16Olúwa sọ fún Mose pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.