Numeri 34:11
Numbers 34:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn.
Numbers 34:11 in English
Numbers 34:11 · Berean Standard Bible
then go down from Shepham to Riblah on the east side of Ain and continue along the slopes east of the Sea of Chinnereth.*
Context
9tẹ̀síwájú lọ sí Sifroni, kí o sì fò pín si ní Hasari-Enani, èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá. 10Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ tiyín ní ìhà ìlà-oòrùn láti Hasari-Enani lọ dé Ṣefamu. 11Ààlà náà yóò ti Ṣefamu sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ribla ní ìhà ìlà-oòrùn Aini, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kinnereti ní ìhà ìlà-oòrùn. 12Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jordani, yóò sì dópin nínú Òkun Iyọ̀.
“ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ” 13Mose pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: Olúwa ti pàṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án, àti ààbọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.