Numeri 26:60
Numbers 26:60 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari.
Numbers 26:60 in English
Numbers 26:60 · Berean Standard Bible
Nadab, Abihu, Eleazar, and Ithamar were born to Aaron,
Context
58Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi;
ìdílé àwọn ọmọ Libni,
ìdílé àwọn ọmọ Hebroni,
ìdílé àwọn ọmọ Mahili,
ìdílé àwọn ọmọ Muṣi,
ìdílé àwọn ọmọ Kora.
(Kohati ni baba Amramu, 59orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. 60Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. 61Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.) 62Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.